Complete CAC Yoruba Hymn 1

695 

Loading.... (view fulltext now)

Loading....

Loading....

Loading....

Loading....

Full text

(1)

76 ORIN OWURO

1. C.M

Ago Re wonni ti li ewa to, Oluwa awon omo Ogun OD. 84:1

1 fp Olus‘agutan eni Re

Fi ara Re han wa, ‗Wo fun wa n‘ile adura M‘okan wa gbadura 2. mf Fi ami ife Re han wa

So ireti wa ji

Se‘ri‘bukun Re s‘ori wa K‘awa le ma yin O 3 mf K‘ife ati alafia

K‘o ma gbe ile yi! F‘irora f‘okan iponju M‘okan ailera le 4 mf F‘eti igbo, aya ‗gbase,

Oju ‗riran fun wa; Tan imole Re lat‘oke K‘a dagba l‘or‘ofe 5 mf K‘a fi gbagbo gbo oro Re

K‘a f‘igbagbo bebe Ati niwaju Oluwa K‘a se aroye wa. Amin

(2)

2. 8.7.8.7

Oluwa fi igbala Re be mi wo OD 106:4 1 f Ife orun lail‘egbe,

Ayo orun sokale,

Fi okan wa se ‗bugbe Re, Se asetan anu Re.

2 Jesu Iwo ni alanu

Iwo l‘onibu ife

cr Fi igbala Re be wa wo M‘okan eru wa duro 3 mf Wa, Olodumare, gba wa

Fun wa l‘ore-ofe Re. L‘ojiji ni k‘o pada wa, Ma si fi wa sile mo; 4 f Iwo l‘a o ma yin titi,

Bi won ti‘nse ni orun Iyin wa ki yoo lopin A o s‘ogo n‘nu ‗fe Re.

5 cr S‘asepe awa eda Re

Je k‘awa lailabawon K‘a ri titobi ‗gbala Re Li aritan ninu Re.

6 f Mu wa lat‘ogo de ogo,

Titi di ibugbe wa; Toa fi ade wa juba Re N‘iyanu, ife, iyin. Amin

(3)

3. L.M

Emi tikara mi yio si ji ni kutukutu. OD 108:2 1 f Ji Okan mi, ba orun ji,

Mura si ise ojo Re. Mase ilora, ji kutu. K‘o san ‗gbese ebo oro

2 Ro gbogb‘ojo t‘o fi sofo

Bere si rere ‗se loni Kiyesi ‗rin re l‘aye yi, Ko si mura d‘ojo nla ni. 3 mf K‘oro re gbogbo j‘otito,

K‘okan re mo b‘osan gangan Mo p‘Olorun nso ona re O mo ero ikoko re. 4 f Nipa ‗mole ti nt‘roun wa

Tan ‗mole na f‘elomiran Jeki ogo Olorun ‗han Ninu ife at‘orun yin 5 f Ji, gbonranu ‗wo okan mi,

Yan ipo re l‘arin angeli‘, Awon ti won nkorin iyin Ni gbogbo igba s‘Oba wa. 6 f Mo ji, mo ji, ogun orun,

Ki isin yin s‘okan mi ji, Ki nle lo ojo aye mi, Fun Olorun mi bi ti yin. AMIN

(4)

4. L.M

Ma rin niwaji mi, ki iwo ki o si pe. Gen. 17:1

1 mf Oluwa mi, mo njade lo, Lati se ise oojo mi; Iwo nikan l‘emi o mo Loro, lero, ati n‘ise

2 Ise t‘o yan mi l‘anu Re,

Jeki nle se tayo tayo, Ki nr‘oju Re n‘nu ise mi, K‘emi si le fi ‗fe Re han

3 Dabobo mi lowo danwo,

K‘opa okan mi mo kuro Lowo aniyan aye yi Ati gbogbo ifekufe. 4 cr Iwo t‘oju Re r‘okan mi,

Ma wa l‘ow‘otun mi titi, Ki nma sise lo l‘ase Re, Ki nfise mi gbogbo fun O. 5 mf Je ki nreru Re t‘o fuye,

Ki nma sora nigba gbogbo Ki nma f‘oju si nkan t‘orun Ki nsi mura d‘ojo‘ogo. 6 f Ohunkohun t‘O fi fun mi,

Je ki nle lo fun ogo Re, Ki n f‘ayo sure ije mi, Ki nba O rin titi d‘orun AMIN

(5)

5 L.M

Nigbawo ni ikwo o to mi wa? OD 101:2

1 mf Wa s‘odo mi, Oluwa mi, Ni kutukutu owuro, Mu k‘ero rere so jade, Lat‘inu mi s‘oke orun

2 Wa s‘odo mi, Oluwa mi,

Ni wakati osan gangan; Ki ‗yonu ma ba se mi mo, K‘o si so osan mi d‘oru. 3 mp Wa s‘odo mi, Oluwa mi,

Nigbati ale ba nle lo, Bi okan mi ba nsako lo, Mu pada, f‘oju ‗re wo mi.

4 Wa s‘odo mi, Oluwa mi,

L‘oru, nigbat‘oru ko si, P Je ki okan aisimi mi,

Simi le okan aya Re. 5 mp Wa s‘oso mi, Oluwa mi,

Ni gbogbo ojo aye mi, p Nigbati emi mi ba pin f Ki nle n‘ibugbe l‘odo Re.

(6)

6 7.7.7.D

Sugbon orun ododo yio la fun eniyan ti O beru oruko Mi. Mal 4:2 1 f Krist‘t‘ogo Re ka aye,

Krist, Imole Otito; Orun ododo dide, K‘o si bori okunkun ‗mole ooro, sunmo mi, ‗Rawo oro yo n‘nu mi 2 mp Ooro to de laisi Re,

Ookun on ‗banuje ni, Ile to mo ko l‘ayo, Bi nko r‘oye anu Re, B‘Iwo ko fi ‗mole Re Kan oju on okan mi 3 mf Nje be okan mi yi wo,

Le okunkun ese lo, F‘imole orun kun mi, Si tu aigbagbo mi ka Maa f‘ara Re han mi si Titi di ojo pipe

(7)

7 S.M.

Li ale, li owuro, ati li osan li emi o ma gbadura OD 55:17 1 mf Wa s‘adura ooro,

Kunle k‘a gbadura, f Adura ni opa Kristian,

Lati b‘Olorun rin 2 mf L‘osan, wole labe

Apat‘ayeraye, p Itura ojiji Re dun

Nigba t‘orun ba mu 3 mf Je ki gbogbo ile

Wa gb‘adura l‘ale; Ki ile wa di t‘Olorun di Ati ‗bode orun

4 p Nigbat‘od‘oganjo,

Je k‘a wi l‘emi pe,

f Mo sun, sugbon okan mi ji, Lati ba O s‘ona

(8)

8. C.M

Yi o fi iye Re bo o OD 91:4

1 mf Imole oro didun yi, Ji mi nin‘orun mi, Baba, ife Tire nikan, Lo pa omo Re mo. 2 mp Nigbogbo oni, mo be O,

Maa se oluso mi, Dariji mi, Jesu mimo, Ki emi je Tire loni. 3 mf Wa se bugbe Re ninu mi,

Emi ore ofe,

So mi do mimo l‘aye yi, K‘emi le roju Re. AMIN

(9)

9 7.7.7.7.3

Ohun mi ni Iwo o gbo li owuro, Oluwa. OD 5:3

1 f Jesu, Orun ododo,

Iwo imole ife ‗Gbati ‗mole Owuro, Ba nt‘ila orun tan wa, Tan ‗mole ododo Re Yi wa ka

2 mp Gege be iri ti nse,

S‘ori eweko gbogbo, K‘Emi ore-ofe Re S‘o okan wa di otun, Ro ojo ibukun Re

p Sori Wa

3 mf B‘imole orun ti nran, K‘imole ife Tire

Si ma gbona l‘okan wa, K‘o si mu wa l‘ara ya K‘a le ma f‘ayo sin O. L‘aye wa.

4 Amona ireti wa,

Ma fi wa sile titi, Fi wa s‘abe iso Re Titi opin emi wa, Sin wa la ajo wa ja S‘ile wa

5 Ma to wa l‘ona toro

L‘ojo aye wa gbogbo Sin wa la ekun re ja, Mu wa de ‗le ayo na

cr K‘a le ba won mimo gba

p Isimi.

(10)

10 6.6.6.6

Gbo ekun mi, Olorun; fiyesi adura mi. OD 61:1

1 mp Baba mi, gbo t‘emi, ‗Wo ni alabo mi, Ma sun mo mi titi, Oninure Julo

2 Kristi Oluwa mi,

Iye at‘ogo mi, Ki ‗gba naa yara de, Ti un o de odo Re.

3 p Olutunnu julo,

‗Wo ti ngbe inu mi, ‗Wo t‘O mo aini mi, Fa mi, k‘O si gba mi 4 mf Mimo, Mimo, Mimo,

Ma fi mi sile lae, P Se mi ni bugbe Re,

Tire nikan laelae. AMIN

(11)

11. C.M

Fi ona re le Oluwa lowo. OD 37:5

1 Lekan si, bi orun ti nran, Awa mbe Olorun

Pe ki ‗mole Re ailopin S‘amona wa loni 2 f K‘a mase da esekese,

K‘a ma si ro ibi; K‘a ni otito gan l‘enu Ati ife l‘okan

3 mf L‘ojo oni, Olugbala, K‘a ri iranwo Re, Di Lati gba wa lowo esu, P Ti nd‘ode wa kiri 4 mf Ki ise wa l‘ojojumo

Ma je fun iyin Re,

Be l‘o ma mbukun ise wa Ta mbere ninu Re. 5 cr Je ka fi iwontunwonsi

Kawo ‗fekufe wa, Ki ‗gberaga asan ara, Ma bori okan wa 6 f Olorun Baba at‘Omo

Ati Emi Mimo Ni ki Eda at‘Angeli F‘ogo ailopin fun. AMIN

(12)

12 9.6.9.6

Abrahamu si sunmo odo Oluwa. Gen. 18:23 1 Je ki nsun mo O l‘ojojumo

Jesu Olugbala

Je ki ngb‘ara le O si, Jesu Ni Gbogbo on li.

2 Je ki n fe Ewa Re han, Jesu, Bi orun lo‘roke

Je ki ete mi so adun Re, Pelu ayo toto,

3 Je ki ndabi orisun omi, Jesu Olugbala

Ma lo mi l0jojumo, Jesu, Fun ogo Re nikan 4 Lokan ati l‘ero mi, Jesu,

J‘oba patapata

Je ki njeni oloto, Jesu, Si O l‘ohun gbogbo.

5 Monk‘ebi at‘ongbe Re, Jesu, Ebi at‘okan wa;

Mo nsaferi ‗le mi ni Sion; Nibit‘Olorun wa.

(13)

13 8.7.11.8.7.11 & Ref

Olorun si wipe, Ki imole ki o wa; imole si wa. Gen. 1:3 1 mf ‗Mole wa l‘afonifoji

‗Mole wa l‘ori oke Jesu l‘O mu wa s‘aye

Okukun yi, ‗Mole wa l‘ara itanna To ndagba l‘eba odo,

Imole wa ni ‗bikibi ti mo nlo; F ‗Mole, Mole t‘ife Re orun,

‗Mole, mole, itansan orun ‗Mole, mole, li aye wa yi, ‗Mole, mole, l‘ona ani

Gbogbo 2 mf Imole wa lori pada

Ati l‘ori koriko

Nibiti awon eye nkorin iyin; Imole wa lori oke,

‗Mole wa ni petele

Je ki gbogbo eda jumo korin ‗yin

3 f B‘aye tile kun fun ‗mole To si ntan l‘ojojumo,

Okan pupo wa n‘nu okunkun Sibe, Ti ko gb‘oruko Jesu ri,

Tabi ife ‗yanu Re, Je ki a fi oro Re ran won

L‘owo AMIN

(14)

14 C.M

Emi dubule, mo si sun‘ mo si ji; Nitori ti Oluwa ti mi l‘ehin. OD 3:5 1 mf Ninu gbogbo ewu oru,

Oluwa l‘o so mi; Awa si tun ri ‗mole yi A tun te ekun ba. 2 Oluwa, pa wa mo l‘oni,

Fi apa Re so wa; Kiki awon ti‘wo pamo, L‘o nyo ninu ewu. 3 K‘oro wa, ati iwa wa,

Wipe, tire l‘awa; Tobe t‘imole otito Le tan l‘oju aye. 4 mp Ma je k‘a pada lodo Re,

Olugbala owon; Titi ao f‘oju wa ri Oju Re li opin.

(15)

15 6.6.11.D

A ti tan ife Olorun ka okan wa lati odo Emi Mimo wa ti a fi fun wa. Rom. 5:5 1 mf Ife orun Sokale,

Tan ka okan mi yi,

Ki o si f‘ore-ofe Re gbogbo Be wo;

F Olutunu Orun,

Mf Farahan n‘n‘Okan mi,

Si mu ki ina mimo Re mu soji 2 mf Je ko ma jo gere,

Ki ‗fekufe d‘eru

T‘ise iyangbo ni waju afefe; F Ki ‗mole ologo

Mf Tire tan yi mi ka,

Si ona mi ati aye mi gbogbo 3 mf Fi ife mimo se

Ewu agbada mi;

Ati iwa ‗rele, awotele mi;

F Fokan mimo toto

Mf Ti irele okan

Mp Tinsokun fun ese mi gbogbo Kun mi

4 mf ‗Gbana okan mi yi Y‘o di alagbara

Lati se ‗fe Re ju b‘a ti lero lo; F Ko s‘eda na t‘o mo

Tor‘ofe okan wa Mf Titi y‘o fi di ite Emi mimo.

(16)

16 L.M

Emi o ma fi otito re han lati irandiran. OD 89:1 1 f Baba, a sope ‗toju Re,

T‘o f‘alafia kun ‗le wa; Odo Re ni won ti san wa Owo Re l‘o si ngbe won ro 2 mf Olorun, t‘o ye k‘a ma yin,

L‘a nkepe ninu ile wa; Oluwa orun, ti ko ko Lati ma gbe ile aye. 3 Jek‘olukuluku ‗dile

Ma kepe O tosan-toru; K‘a ko omo at‘om‘odo L‘ofun at‘ore-ofe Re. 4 f Beni k‘iran ti mbo ma so

T‘ola ooko Re t‘o logo, Titi gbogbo wa y‘o fi lo Dapo mo idile t‘orun AMIN

(17)

17 C.M

Ona mi iba je la sile lati ma pa olana Re Mo! OD119:5 1 mf Oluwa, emi y‘o korin

Anu at‘idajo;

Nigbawo n‘Iwo y‘o fun mi N‘imole on iye

2 mo nfe lati t‘ona pipe, Ki nni okan pipe, Ona, okan ati ile, Nibiti Iwo mbe, 3 Mo nfe ki awon oloto

Je oluranwo mi; Ki nfi won s‘ore-imule A t‘omo-odo mi. 4 cr Ki yo si eke at-etan

Ninu ibugbe mi; Mp Oluwa, Jek‘Ibugbe mi

Ye fun O lati gbe! AMIN

(18)

ORIN ALE 18 8.7.8.7

Emi o ma korin anu Oluwa lailai. OD 89:1 1 f L‘ojojumo l‘a ngbe O ga

Nigbati ile ba mo, T‘a ba kunle lati yin O Fun anu ti owuro 2 L‘ojojumo l‘angbe O ga

Pel‘orin n‘ile-eko, Lojojumo, pelu iyin, L‘a nse ise wa gbogbo. 3 L‘ojojumo l‘a ngbe O ga

Ninu orin k‘a to sun

Awon Angel‘gbo, won si nso Awon aguntan Kristi

4 L‘ojojumo l‘a ngbe O ga Ki se ni iyin lasan; Otito ati igboran Nf‘ogo Re han ninu wa. 5 mf L‘ojojumo l‘a ngbe O ga

Gba t‘a ngbiyanju fun krist‘ Lati ma farada iya

K‘a pa ese run n‘nu wa. 6 f L‘ojojumo l‘a ngbe O ga

Tit‘ ojo wa y‘o fi pin Tao simi n‘nu lala gbogbo L‘alafia d‘ojo Re

(19)

19 L.M

Nigbati iwo ba sun, yio ma so O. Owe 6:22 1 f Ogo f‘Olorun l‘ale yi

Fun gbogbo ore Imole, So mi, Oba awon Oba L‘abe ojiji iye Re. 2 mp Oluwa f‘ese mi ji mi,

Nitori omo Re, loni K‘emi le wa l‘alafia, Pelu iwo ati aye

3 mf Je k‘okan mi le sun le O, K‘orun didun p‘oju mi de, Orun ti y‘o m‘ara mi le, Ki nle sin O li owuro 4 mp Bi mo ba dubule laisun,

F‘ero orun kun okan mi, Ma je ki nl‘ala bururu, Ma je k‘ipa okun bo mi 5 ff Yin Olorun, Ibu ore;

E yin, eyin eda aye, E yin, eyin eda Orun, Yin Baba, Omo on Emi AMIN

(20)

20 6.4.6.6

Je ki adura mi ki o wa si iwaju Re bi ebo asale. OD 141:2 1 mp Orun fere wo na,

Ojo lo t Cr K‘ife k‘o ji dide

Ko rubo asale 2 pp Bi Jesu l‘origi,

Ti teriba, T‘O jowo emi Re Le Baba Re lowo 3 mf Be ni mo f‘emi mi

Fun l‘a fun tan, Ni ‗pamo re mimo L‘emi gbogbo sa wa 4 mp Nje emi o simi

Lodo Re je, Laije k‘ero kan so Yo okan mi lenu

5 ‗Fe Tire ni sise

L‘onakona; Mo d‘oku s‘ara ni Ati s‘ohun gbogbo 6 mf Be l‘emi ye; sugbon

Emi ko, On

Ni mbe laye n‘nu mi, L‘agbara ife Re.

7 f Metalokan mimo,

Olorun kan Lae ki nsa je Tire K‘On je t‘emi titi AMIN

(21)

21 8.7.8.7.7.7

Eni ti npa o mo ki yio togbe. Od. 121:3 1 f Ife Re da wa si loni,

Lare, a si dubule, Ma so wa ni ‗dake oru, K‘ota ma yo wa l‘enu Jesu, se Olutoju wa; Iwo l‘o dun gbekele 2 Ero at‘elajo l‘aye

A ngb ‗arin awon ota; Yo wa, at‘ile wa l‘weu; Lapa Re ni ka sun si; P N‘ijo iyonu aye pin;

K‘a le simi l‘odo Re

(22)

22 10.10.10.10

Ba wa duro: nitori o di ojo ale. Lk 24:29 1 mf Wabami gbe, ale fere le tan;

Okunkun nsu, Oluwa ba mi gbe Bi Oluranlowo, miran ba ye, Iranwo alaini, Wa ba mi gbe. 2 p Ojo aye mi nsare lo s‘opin

Ayo aye nku, ogo re nwomi, Ayida at‘ibaje ni mo n ri, cr ‗Wo ti ki yipada, wa ba mi gbe. 3 mp Ma wa l‘eru b‘Oba awon oba

B‘oninure, wa pelu ‗wosan Re, Ki O si ma kanu fun egbe mi, Wa, Ore elese, wa ba mi gbe. 4 Mo n fe O ri, ni wakati gbogbo

Kilo le segun esu b‘ore Re? Tal‘o le se amona mi bi Re? N‘nu ‗banuje at‘ayo ba mi gbe. 5 mf Pelu ‗bukun Re, eru ko ba mi

Ibi ko wuwo, ekun ko koro, F Oro iku da? Segun isa da?

Un o segun sibe, b‘Iwo ba mi gbe 6 p Wa ba mi gbe, ni wakati iku,

Cr Se ‗mole mi si toka si orun F B‘aye ti nkoja, k‘ile orun mo, Fp.mp Ni yiye, ni kiju, wa ba mi gbe.

(23)

23 L.M

Emi o dubule pelu li alafia, emi o si sin. OD 4:8 1 mf Iwo imole okan mi,

Ni odo Re, oru ko si, Ki kuku aye ma bo O, Kuro l‘oju iranse Re. 2 pp Ni gbat‘orun ale didun

Ba npa ipenpe ‗ju mi de, K‘ero mi je lati simi, Lae l‘aya Olugbala mi. 3 mf Ba mi gbe l‘oro tit‘ale

Laisi Re, emi ko le wa, P Ba mi gbe ‗gbat‘ile ba nsu,

Laisi Re, emi ko ke ku. 4 mp Bi otosi omo Re kan

Ba tapa s‘oro Re loni, Cr Oluwa, sise ore Re,

Ma je k‘o sun ninu ese 5 mf Bukun fun awon alaisan,

Pese fun awon talaka, Di K‘orun onirobinuje Pp Dabi orun omo titun 6 cr Sure fun wa ni gbat‘a ji

Ka to m‘ohun aye yi se F Titi awa de ‗b‘ife

Ta o si de Ijoba Re. AMIN

(24)

24 L.M

Nigbati o di asale, nwon kogbogbo Awon Alaisan to o wa. MK 1:32 1 mf L‘oju ale ‗gba‘t orun wo,

Won gbe abirun w‘odo Re, P Oniruru ni asisan won, F Sugbon won f‘ayo lo‘ le won 2 mf Jesu l‘ oj‘ale yi,

A sun m‘O t‘awa t‘arun wa, Cr Bi a ko tile le ‗ri O,

Sugbon, a mo p‘O sunmo wa. 3 mp Olugbala, wo osi wa,

Opo nsaisan, opo nk‘edun, Opo ko ni ‗fe si O to. Opo n‘ife won si tutu.

4 Opo ti ri p‘asan l‘aye

Sibe nwon ko f‘aye sile, Opo l‘ore b n‘inu je, Sibe won ko fi O s‘ore

5 Ko s‘okan ninu wa t‘o pe

Gbogbo wa si ni elese, Awon t‘o si nsin O toto Mo ara won ni alaipe 6 mf Sugbon Jesu, Olugbala,

Eni bi awa ni ‗Wo se ‗Wo ti ri‘danwo bi awa ‗Wo si ti mo ailera wa.

7 Agbar‘owo Ro wa sibe,

Ore Re si ni agbara, P Gbo adura ale wa yi, Cr Ni anu, wo gbogbo wa san.

(25)

25 10.10.10.10

Emi o dide, emi o si to baba mi lo. LK 15:18 1 mp Baba, a tun pade l‘oko Jesu,

A si wa teriba lab‘ese Re, A tun fe gb‘ohun wa s‘oke si O Lati wa anu, lati korin ‗yin 2 f Ayin O fun itoju ‗gba gbogbo

Ojojumo l‘a o ma rohin ‗se Re, Wiwa laye wa, anu Re ha ko Apa Re ki O fi ngba ‗ni mora. 3 p O se! A ko ye fun ife nla Re,

A sako kuro lodo Re poju, Mf Sugbon kikan kikan ni o si npe

Nje a de a pada wa ‗le Baba 4 mp Nipa ooko t‘ob‘or‘ohun gbogbo

Nipa ife t‘o ta‘fe gbogbo yo Nipa eje ti a ta fun ese, Cr Silekun anu, si gba ‗ni s‘ile

AMIN 26 10.4.10.4.10.10

Li osan pelu, o fi awosanma se amona Won ati li Oru Gbogbo pelu imole ina

1 mp ‗Wo imole larin okun aye, Ma sin mi lo;

Okunkun su, mo si jinna s‘ile, Ma sin mi lo;

Cr Nko s‘aferi ola bi y‘o ti ri, To ese mi, ‗sise kan to fun mi, 2 p Nigba kan ri, emi ko be O pe

K‘O sin mi lo,

Beni nko fe O, sugbon nigba yi, Ma sin mi lo,

Afe aye ni mo si nto leyin, Sungbon Jesu, ma ranti igba ni.

3 mf Ipa Re l‘o ti nid mi mu, y‘o si Ma sin mi lo. Ninu ere ati yangi aye,

Ma sin mi lo

Titi em‘o fi ri awon wonni Ti mo fe, ti won ti f‘aye sile

(26)

27 8.7.8.7

Kiyesi, eniti npa Isreali mo kii togbe, Beni Ki I sun. OD 121:4 1 mp K‘a to sun, Olugbala wa,

Fun wa n‘ibukun ale, A jewo ese wa fun O, Iwo l‘O le gba wa la. 2 cr B‘ile tile ti su dudu,

Okun ko le se wa mo, Mf Iwo Eniti ki ‗sare,

Nso awon eniyan Re. 3 p B‘iparun tile yi wa ka,

Ti Ofa nfo wa koja, Mf Awon Angeli yi wa ka, P Awa o wa lailewu. 4 p Ma ko wa, ma fi wa sile,

K‘agbara wa di otun, Ki imole oro ji wa, E K‘a le ma fe ise Re. 5 N‘irele awa fara wa,

S‘abe abo Re, Baba, Jesu, ‗Wo t‘O sun bi awa, Se orun wa bi tire

6 Emi mimo, rado bo wa, Tan‘ mole s‘okunkun wa, Cr Tit‘awa o fi ri ojo

F Imole ayeraye.

AMIN 28 8.8.8.D

Nitori Oluwa yio je imole ainipekun Fun O. Isa. 60:20 1 mf Jesu, bukun wa k‘a to lo,

Gbin oro Re si wa lokan; K‘o si mu k‘ife gbigbona Kun okan ilowowo wa, Cr Nigba yiye at‘iku wa, P Jesu jare, se ‗mole wa. 2 mp Ile ti su, orun ti wo,

‗Wo si ti siro iwa wa, Die nisegun wa loni,, Isubu wa lo p‘apoju

(27)

3 mf Jesu, dariji wa, fun wa L‘ayo ati eru mimo At‘okan ti ko l‘abawon, Ka ba le jo Ol‘ajo tan. 4 mp Lala dun, tori‘Wo se ri; Aniyan fere, O se ri, Ma je k‘a gbo t‘ara nikan, K‘a ma bo sinu idewo 5 mp A mbe O ‗awon alaini,

F‘elese at‘awon t‘a fe, Je ki anu Re mu wa yo, ‗wo Jesu l‘ohun gbogbo wa. 6 mf Jesu bukun wa, ile su,

Tikara Re, wa ba wa gbe, Angel‘ ere nso ile wa A tun f‘ojo kan sunmo O AMIN

29 9.8.9.8

Ati lati duro li orowuro lati dupe, ati lati Yin Oluwa ati be gege li asale. I Kro. 23:30 1 mf Oluwa, ojo to fun wa pin,

Okunkun si de l‘ase Re, ‗Wo l‘a korin owuro wa si, Iyin Re y‘o m‘ale wa dun. 2 mf A dupe ti ijo Re ko sun,

B‘aye ti nyi lo s‘imole, O si nsona ni gbogbo aye, Ko si simi t‘osan-t‘oru. 3 B‘ile si ti nmo l‘ojojumo,

Ni orile at‘ekusu, Ohun adura ko dake ri, Be l‘orin iyin ko dekun 4 Orun t‘o wo fun wa, si ti la,

S‘awon eda iwo-orun, Nigbakugba li enu si nso Ise ‗yanu Re di mimo 5 cr Be, Oluwa, lae n‘Ijoba Re,

Ko dabi ijoba ye; F O duro, o si nse akoso,

Tit‘ida Re o juba Re.

(28)

30 7.6.7.6.8.8 Nitori ojo nlo. Jer. 6:4

1 Ojo oni koja lo, A dupe, Oluwa, Jo, gba wa lowo ese Ni wakati oru,

Di Jesu, jo, f‘iso Re so wa, Cr Si mu wa la oru yi ja. 2 mf Ayo oni koja lo,

A gb‘okan wa s‘oke Jo, ma je k‘a n‘ikose Ni wakati oru;

Di Jesu, jo fun wa n‘imole, Cr Si mu wa la oru yi ja 3 mf Lala oni koja lo,

A fi orin yin O, Jo, ma je k‘a ri ewu Ni wakati oru;

Di Jesu, jo f‘is Re so wa, Cr Si mu wa la oru yi ja. 4 mf S‘Olupamo wa, Baba,

Nitori; Wo l‘O mo Gege b‘ewu ti po to, Ti a o ba pade;

Di Jesu, Olufe, gbo ti wa, Cr Si mu wa la gbogbo won ja.

AMIN 31 8.8.8.4

Oorun ki yio pa o nigba Osan, tabi osupa nigba oru. OD 121:6 1 mf Oro didan ti rekoja;

Wawa l‘akoko na fo lo, Di Bi osan si ti nkoja lo,

Nile nsu bo.

2 mf Kukuru, l‘ojo aye wa, Were l‘osan re nde opin; Krist‘ Wo ti se Ona iye, Sin wa de ‗le.

3 cr Jo fi ore-ofe Re nla Gbe okan wa b‘ilu t‘erun; Je k‘a ma wo ‗le didan ni Ti mbe l‘oke.

4 f Nibi ‗mole, iye ayo At‘ alafia gbe njoba,

(29)

T‘awon angel‘ ko dekun ‗ko Orin iyin.

5 f T‘awon mimo wa ‗so ala, Ti okunkun ale ki su, Ti ‗Wo ‗Mole ayeraye Je Oluwa.

AMIN 32 8.3.3.8

Emi o ma yin O tinu-tinu mi gbogbo. OD 138:1 1 mp Ki nto sun, fun ore t‘oni

T‘Olorun Se fun mi, Cr Un o yin Olugbala 2 mf Oluwa, kini un o fi yin

Oko Re, T‘o kun fun Anu ati Ore. 3 mf Iwo ti s‘eto irin mi,

L‘ona Re Di ‗ Wo gb‘ebe;

‗Wo si gba ise mi 4 mp Ma ko mi, ma fe mi titi;

F‘alafia Re fun mi, Titi ‗Wo y‘o pe mi 5 mf ‗Wo apata at‘odi mi,

F‘ipa Re Pa mi mo

‗gba m‘ba dubule sun. 6 p Nigbakugba ti mo ba ku,

Cr Je k‘emi

Ji dide

F Pelu awon mimo.

AMIN

33 7.7.7.7.7.7

Iwo o pa mo li alafia pipe, okan eniti o simi le O. Isa. 26:3 1 mf L‘alafia l‘olorun

Sin wa ja ose miran; E je k‘a bere ‗bukun L‘ojo ‗simi ti mbo yi,

(30)

Ojo t‘o tobi jule, Apere ayeraye.

2 f K‘a sope opo aanu

Ti a ri gba l‘ose yi; Olodumare so wa, O bo wa, O si to wa, Di B‘a ti s‘alaimore to, Ta nfi ese s‘esan fun. 3 mp B‘a ti ntoro ifiji

L‘oruko Olugbala, Fi oju anu Re han, Le Ese on ‗tiju lo, Gba wa lowo aniyan K‘a le sun l‘alafia. 4 mf ‗Gbati ile ba si mo,

Je k‘a mo p‘o wa n‘tosi Je k‘a le ri ogo Re ‗Gbat‘a be de ile Re, Cr Nibe, Oluwa fun wa

N‘itowo ase orun 5 mf Jek‘iro ‗hinrere Re

Gb‘elese at‘oloto; Cr K‘eso or‘ofe ma po,

K‘o tan gbogbo arun wa, F K‘ojo ‗simi ma ri be

Tit‘ao de ijo t‘orun 34 7.7.7.7.4 & Ref

Emi o gbe leke, nitori ti o mo oruko mi. OD 91:14 1 mf Orun ti de iwo re,

‗simi nt‘orun bo w‘aye; Wa ka josin bi ale Ti ntan ‗na fitila re Loju sanma

Mp Mimo, mimo, mimo Oba Ogo, Torun-taye kun fun O, F Torun-taye l‘o nyin O,

Oga ogo 2 mp Oluwa iye, labe

Orun ti se ‗bugbe Re, Ko awa ti nw‘oju Re Jo sin‘agbo ife Re; ‗Wo mbe n‘tosi.

(31)

3 Bi ile si ti nsu lo, ‗Wo t‘o f‘ife d‘aye mu L‘okan wa nwa, rekoja Ogo at‘ewa ‗rawo To boju Re. 4 mf Gba irawo at‘osan,

At‘oru ki o si mo, Oluwa awon agenl‘, Je kari ‗mole aye Ki okun pin. AMIN 35 7.7.7.7

Iwo ti ngbo adura, si odo re ni gbogbo eniyan mbo. OD 65:2 1 mf Agboju s‘oke si O,

At‘owo ati okan; Tewogba adura wa, P B‘o tile se ailera. 2 Oluwa je k‘a mo O,

Je k‘a mo oruko Re; Je k‘awa se ife Re, Bi won ti nse li orun 3 mp Nigbati a sun l‘oru

So wa k‘o duro ti wa; F Nigbati ile si mo, Ff K‘a ji, k‘a fi ‗yin fun O.

AMIN 36 6.5.6.5

Jesu si duro larin, O ni, ‗Alafia fun Nyin‘. Jn., 20:26 1 mf Jesu wa s‘arin wa,

L‘agbar‘ajinde, Je k‘isin wa nihin Je isin owo. 2 mp Mi Emi Mimo Re

Sinu okan wa, Cr Mu ‗foya at‘aro Kuro lokan wa. 3 f Bi a ti nyara lo,

L‘ona ajo wa, K‘a ma sona f‘oro T‘ojaeraye. AMIN

(32)

37 13.10.13.10

E ma sin Oluw Ewa iwa mimo. OD 96:9

1 mf E sin Oluwa ninu ewa iwa mimo Wole fun k‘esi pokik‘ ogo Re Pelu wura ‗gboran ati turari ‗rele W wole fun Un k‘e si juba Re. 2 Gbe eru aniyan yin lele lese Re

Y‘o si ti ka Re ba yin gbe d‘ori; Y‘o tu o ninu, yo si gbo adura re, Y‘o to ‗sise re bo ti to fun o

3 Ma beru lati wo agbala Re, pelu Kiun ninu oro t‘o le pe n tire; Cr Ewa otito ati ife owuro, F ebo wonyi la nbere lowo re

4 mf B‘a tile m‘awon wonyi wa ni ‗wariri Cr On y‘o gba won l‘oruko to sowon, F ayo owuro y‘o dipo ekun ale

Ireti kikun y‘o dipo eru.

5 mf E sin Oluwa ninu ewa iwa mimo, Wole fun k‘e si pokik‘ogo Re Pelu wura ‗gboran ati turari ‗rele. E wole fun Un ke si juba Re.

AMIN 38 C.M

E wa, e je ki a korin si Oluwa. OD95:1 1 mf E wa k‘a korin s‘Oluwa,

Olukuluku wa; F Ki a ho iho ayo si

Apata ‗gbala wa. 2 e je k‘a wa siwaju Re

Pelu ‗yin at‘ope; Ka ko orin pel‘ore ofe, Ka si yo ayo nla. 3 ff Olorun yi tobi l‘Oba

J‘awon orisa lo;

Gbogbo‘aye wa nikawo Re At‘awon oke nla

4 f Tire li awon okun nla, On ni O si da won; Ati ‗yangbe ile pelu, Owo Re lo si da.

(33)

5 mf E wa, e je ki a wole Ki a teriba fun, Ki a si kunle niwaju Oluwa Eleda. AMIN 39 S.M & Refrain

Eniti enyin fe lairi. 1 Peter 1:8 1 f Eyin te fe Oluwa,

E fi ayo yin han, E jumo ko orin didun, E jumo ko orin didun K‘e si y‘ite na ka, K‘e si y‘ite na ka Ff A nyan lo si Sion‘

Sion‘ to l‘ewa jule A nyan goke lo si Sion‘, Ilu Olorun t‘o l‘ewa 2 f Je k‘awon ni ma korin

Ti ko m‘Olorun wa, Sugbon awon omo Oba, Sugbon awon omo Oba, Y‘o royin ayo won, Y‘o royin ayo won.

3 Oke Sion‘l‘o nmu

Egberun adun wa

Ki a to de gbangba orun Ki a to de gbangb‘orun Pelu ‗ta wura re, Pelu ‗ta wura re. 4 mf Nje ka ma korin lo,

Cr K‘omije gbogbo gbe F A nyan n‘ile Immanuel‘

A nyan n‘ile Immanuel‘, Ff S‘aye didan loke,

S‘aye didan loke

AMIN 40 D.S.M

Eniti enyin fe lairi. 1 pet 1:8 1 f Eyin t‘e f‘Oluwa,

E fi ayo yin han; E jumo ko orin didun B‘e ti ny‘ite Re ka;

(34)

Jek‘awon ‗ni dake Ti ko m‘Olorun wa;

Sugbon k‘awon ‗ranse Oba Ma ro ayo won ka.

2 Olorun t‘o joba, Ti nwo gbogbo aye Ti ngu awosanmo l‘esin Ti nmu ‗ji pa roro; Ff Tiwa l‘Olorun yi

Baba Olufe wa;

Y‘o ran agbara t‘orun wa Lati gbe wa soke

3 mf Nibe, l‘ao r‘oje Re, T‘a ki o dese mo;

T‘ao si ma jadun ailopin, Nipa or‘ofe Re;

Cr Loto, k‘a to jinde Si iye ailopin, Ero irora nlanla na F Ninu Ayo wa bi si. 4 Eni-or‘ofe ri

‗Bere ogo laye; Eso orun ngberu laye N‘nu gbagbo on ‗reti: Cr Nje k‘orin wa goke,

K‘omije gbogbo gbe; F A nkoja lo n‘le ‗manuel‘

S‘aye rere loke.

AMIN 41 13.9.13.9 & Ref.

E ma ba ara nyin soro ninu psalmu, ati orin iyin ati orin Emi. Efe. 5:9 1 mf Ko su wa lati ma ko orin igbani

F Ogo f‘Olorun aleluya!

A le fi igbagbo korin na s‘oke kikan. f Ogo f‘Olorun aleluya!

A le fi igbagbo korin na s‘oke kikan. Ff Ogo f‘Olorun, Aleluya

Mf Omo Olorun ni eto lati bu s‘ayo Pe ona yi nye wa si,

Okan wa ns‘aferi Re;

Nigb‘o se a o de afin Oba wa Ologo F Ogo f‘Olorun, Aleluya!

2 mf Awa mbe n‘nu ibu ife t‘o ra wa pada, F Ogo f‘Olorun Aleluya!

(35)

Mf Awa y‘o fi iye goke lo s‘oke orun; F Ogo f‘Olorun, Aleluya!

3 mf Awa nlo si afin kan ti a fi wura ko, F Ogo f‘Olorun Aleluya!

Nibiti ao ri Oba Ogo n‘nu ewa Re, Ff Ogo f‘Olorun, Aleluya!

4 mf Nibe ao korin titun t‘anu t‘O Da wa n de, F Ogo f‘Olorun Aleluya!

Nibe awon ayanfe yo korin ‗yin ti Krist;

Ff Ogo f‘Olorun, Aleluya!

AMIN 42 C.M

Eyi li ojo ti Oluwa da. OD 118:24

1 mf Wa, je k‘a jumo f‘ohun kan Korin yi ite ka;

Oni l‘ojo t‘Oluwa da T‘o si pe ni Tire. 2 f Ojo yi l‘Olorun bukun,

Larin ojo meje; Apere ‗simi ailopin T‘awon t‘orun ngbadun, 3 Nje k‘a ma korin oko Re

K‘a ma reti ojo T‘Oludande y‘o sokale T‘asan aye y‘o pin. 4 Lojojumo titi aye

Ni ki a ma korin; K‘a ma yo ninu Oluwa Titi ayeraye.

AMIN 43 L.M

Oluwa yio fun ni li ore-ofe ati ogo: ko si ohun rere ti yio fa Sehin lowo awon ti nrin dede. OD 84:11

1 mp Oluwa gbo adura wa N‘nu le Re l‘ojo mimo li; Bi ebo ope n‘ile yi K‘orin wa je itewogba. 2 cr Oluwa, isimi Re dun

Sugbon t‘oke ju t‘aye lo; Sibe Pelu ‗reti ayo

(36)

3 mf Ko si are, ko si ise, Ese, iku ki y‘o de ‗be, Ohun irora ki y‘o dun Nibiti ahon aiku wa. 4 f Ko si adagiri ota,

Isimi laisi aniyan, Oju ojo ko su nibe, Osan gangan ayeraye. 5 mf Bere, Ojo t‘a ti nreti,

Mo si aye irora yi, Ao f‘ayo rin l‘ona t‘ayo Ao si sun ninu Oluwa

AMIN 44 7.6.7.D.

Mo wa ninu emi li ojo Oluwa. Ifi. 1:10 1 f Ojo ‗simi at‘ayo

Ojo inu didun, Itunu fun ‗banuje Ojo dida julo, Ti awon eni giga Niwaju ite Re,

P Nko Mimo, Mimo, Mimo, S‘Eni Metalokan. 2 f L‘ojo yi n‘imole la,

Nigba dida aye, Ati fun igbala wa, Krist‘ jinde n‘nu oku Mf L‘ojo yi li Oluwa

Kan Emi t‘orun wa, Ojo Ologo julo T‘a tan ‗mole pipe 3 mf Ebute abo ni O

Larin iji aye; Ogba didara ni O Nib‘omi iye nsan Orisun ‗tura ni O Laye aginju yi; L‘ori re, bi ni pisga L‘a nwo ‗le ileri. 4 mp L‘oni s‘ilu t‘ara nu

Ni manna t‘orun nbo Si ipejopo mimo N‘ipe fadaka ndun,

(37)

N‘ibiti ihinrere Ntan imole mimo Omi iye nsan jeje Ti ntu okan lara. 5 k‘a r‘ore-ofe titun

L‘ojo ‗simi wa yi K‘a si de ‗simi t‘o ku F‘awon alabukun, Nie k‘a gbo ‗hun soke Si Baba at‘Omo; Ati si Emi Mimo N‘iyin Metalokan.

AMIN 45 L.M

Nitori omo eniyan je Oluwa ojo isimi. Mat. 12:8 1 f Oluwa ojo Isimi

Gbo eje wa nihin, loni, Gba orin iyin ti a nko Be ebo ope wa si O 2 A fe isimi t‘aye yi

Sugbon ‗simi t‘orun dun ju; Eyi ni l‘okan wa nle pa; Pelu itara on ife. 3 mf Ko saare mo tab‘iponju

Ese tab‘egbe kio de ‗be; Ose ki y‘o dapo merin Ti awon eni aiku nko 4 ko si idagiri ota,

Beni ko s‘ipaya nibe; Ko si oru, ko s‘ikuku; Mf Afi osan titi lae lae. 5 Bere, Ojo t‘a ti nreti,

Afemoju re l‘a fe ri, A fe yo! Lona ise yi K‘a si de ibi ‗simi na.

AMIN 46 6.6.6.6.D

Oni li ojo isimi fun Oluwa. Eks. 16:25 1 mf Jesu, a fe pade

L‘ojo re mimoyi, Mf A si ‗ite Re ka L‘ojo Re mimo yi

(38)

Ff Wo ore wa orun, Adura wa mbo wa, Mf Bojuwa emi wa,

L‘ojo Re mimo yi. 2 f A ko gbodo lora L‘ojo Re mimo yi Li eru a kunle L‘ojo Re mimo yi Ma to gbogb‘ero wa, K‘Iwo k‘o si ko wa K‘a sin O b‘oti ye L‘ojo Re mimo yi. 3 f A teti s‘oro Re

L‘ojo Re mimo yi, Buku oro t‘a gbo L‘ojo Re mimo yi, Ff Ba wa lo ‗gbat‘a lo,

F‘ore igbala Re Si aya wa gbogbo L‘ojo Re mimo yi.

AMIN 47 L.M

Oluwa busi Ojo meje, o si ya si mimo. Eks. 20:11 1 f Ojo mefa t‘ise koja

Okan t‘isimi si bere, Wa okan mi si ‗simi re, Yo s‘ojo t‘Olorun busi 2 f Olorun, a yo si ‗se Re,

L‘oniruru t‘ogbo t‘o otun; A fi ‗yin ro anu t‘o lo, A ni ‗reti s‘eyi ti mbo. 3 Ki ‗ronu at‘ope wa nde,

Bi ebo turari s‘orun, K‘o le fa inu didun wa T‘o je teni t‘o mo nikan 4 Ibale aya orun yi,

L‘eri isimi t‘o logo; To wa fun eniyan mimo, P Opin aniyan at‘aisan.

AMIN 48 C.M

E yi li ojo ti Oluwa da; awa o ma yo inu wa yo si ma dun ninu Re. OD 118:28 1 f Eyi l‘ojo t‘Oluwa da,

(39)

Korun k‘o yo, k‘aye ko yo K‘iyin yi ‗te na ka.

2 loni O jinde n‘nu oku, Ijoba satan ‗tu

‗Won mimo tan ‗segun Re ka Won ns‘oro ‗yanu Re. 3 ff Hosana si Oba t‘a yan

S‘omo mimo Dafid‘, Mf Oluwa, jo sokale wa

T‘Iwo t‘igbala Re. 4 Abukun l‘Oluwa t‘o wa

N‘ise ore-ofe

T‘o wa l‘oruko Baba Re, Lati gba ran wa la. 5 ff Hosana ki ohun goro,

L‘orin ijo t‘aye,

Orin t‘oke orun l‘ohun, Yio dun ju be lo.

AMIN 49 L.M

Nitori Iwo, Oluwa li o ti mu mi yo nipa Ise re. OD 92:4 1 f Didun ni ‗se na, Oba mi,

Lati ma yin Oruko Re, Lati se ‗fe Re l‘owuro Lati so oto Re l‘ale. 2 p Didun l‘ojo ‗simi mimo,

Lala ko si fun mi l‘oni, Okan mi ‗ba le ma korin Bi ohun duru Dafidi! 3 p Okan mi o yo n‘Oluwa,

Y‘o yin ise at‘oro Re Ise ore Re ti po to! Ijinle si ni imo Re. 4 mf Emi o yan ipo ola

‗Gb‘ ore ofe ba we mi nu, Ti ayo pupo si ba mi Ayo mimo lat‘oke wa.

5 f ‗Gbana un o ri, un o gbo, un o mo Ohun gbogbo ti mo ti nfe,

Gbogbo ipa mi y‘o dalu Lati se ife Re titi.

(40)

AMIN 50 7.7.7.7

Nitorina, isimi kan ku fun awon eniyan Olorun. Heb. 4:9 1 mf K‘ojo ‗simi yi to tan,

K‘a to lo f‘ara le le, Cr Awa wole lese Re, Di A nkorin iyin si O. 2 mf Fun anu ojo oni,

Fun isimi l‘ona wa, F ‗Wo nikan l‘a f‘ope fun,

Oluwa at‘Oba wa, 3 p Isin wa ko nilari

Aura wa lu m‘ese, Sugbon ‗Wo l‘o nfese ji Or‘-ofe Re to fun wa. 4 mf Je k‘ife Re ma to wa, B‘a ti rin ‗nu aye yi, Mp Nigbat‘ajo wa ba pin,

K‘a le simi l‘odo Re. 5 f K‘ojo ‗simi wonyi je

Ibere ayo orun, B‘a ti nrin ajo wa lo Si ‗simi ti ko lopin.

AMIN 51 S.M

Yio si dabi imole oro nigbati orun ba la ati ti ko ni kuku. II Sam. 23:4 1 f O jo mole l‘eyi,

Mf Ki ‗mole wa loni,

Cr ‗Wo orun ran s‘okunkun wa, K‘o si le oru lo.

2 p Ojo ‗simi l‘eyi Mf S‘agbara wa d‘otun Di S‘ori aibalo aya wa Mp Se ‗ri itura Re. 3 p Ojo alafia,

Mf F‘alafia fun wa:

Cr Da iyapa gbogbo duro, Si mu ija kuro.

4 p Ojo adura ni; Mf K‘aye sunmo orun;

(41)

Si pade wa nihin. 5 f Oba Ojo l‘eyi;

Mf Fun wa ni isoji; Ff Ji oku okan wa s‘ife;

‗Wo asegun iku.

AMIN 52 S.M

Emi o si bere lowo Baba, oun o si fun Yin li Olutunu miran, ki o le ma ba yin gbe titi laelae. Jn. 14:6 1 f Emi wa ba wa pe,

L‘ojo isimi yi;

Laisi Re awa ko le sin, A ko le gb‘adura 2 f Asan li orin wa,

Iwasu wa asan, Ipejopo wa ko l‘ere Afi b‘O pelu wa. 3 f Ojise Orun nla,

Tani mo je bi Re? Tikalare wa Nipa iranse Re. 4 f Wa ko wa lati be,

L‘ohun t‘a ba toro; Si mu ‗bere wa to jesu T‘a be l‘oruko Re. 5 mf Nipa ‗ranlowo Re

L‘a n‘ireti anu, Isin wa ko le sai l‘ere B‘Iwo ba pelu wa.

AMIN 53 C.M

Mo wa ninu emi li ojo Oluwa. Ifi. 1:10 1 f Je k‘a yin Oluwa ‗simi

Pelu awon mimo, Ti n f‘ayo at‘orin didun Lo ‗simi ailopin

2 mf Oluwa, b‘a ti nranti Re N‘ibukun wa npo si; Nipa orin iyin l‘a nko B‘a ti y‘ayo ‗segun 3 Lojo ayo yi l‘Olorun,

(42)

Oro ayeraye,

F‘ise nla han, t‘o logo ju Ti iseda aye

4 f O jinde, eni f‘irora Di Ra gbogb‘eda pada;

Ise nla ni dida aye, P Idande ju yi lo.

AMIN 54 C.M

Ranti Ojo isimi, lati ya a simimo. Eks. 20:8 1 f B‘o ti dun to l‘oj‘owo yi,

Ojo t‘adara ju Ki a pa ‗ronu aye ti, K ronu nkan t‘orun! 2 mf B‘o ti dun to lati l‘aye

Bebe fun ‗dariji! K‘a fi igboya omo pe ―Baba ti mbe l‘orun‖ 3 Lati gb‘or‘ alafia didun

Lat‘enu ranse Re; P Lati mu k‘a sokun ese,

K‘a ri ona orun 4 p B‘o ba si je pe o ti wa

Lati le ese lo,

Eni t‘o nwo inu okan, Y‘o ran or‘ ofe wa 5 f Nje ma wole ojo owo,

Ojo t‘o dara ju, T‘okan pe lati san eje Im‘ore fun orun.

AMIN 55 S.M

Ranti ojo isimi, lati ya a simimo. Eks. 20:8 1 f Olorun wa orun,

T‘o fi ojo mefa

Da nkan gbogbo ti mbe laye Simi n‘ijo keje

2 f O pase k‘a bowo Fun ojo isimi; Ibinu Re tobi pupo S‘awon t‘o rufin yi.

(43)

3 Awon baba nla wa, P Ti ku nin ‗okunkun;

Won je ogbo aborisa Won ko mo ofin re 4 mf Awa de Oluwa,

Gege bi ase Re; Leyin ise ojo mefa, Lati se ife Re. 5 mf Mimo l‘ojo oni,

O ye ki a simi, K‘a pejo ninu ile Re, K‘a gbo ‗ro mimo Re.

6 Isimi nla kan ku

F‘awon eniyan Re; Om‘ Olorun, Alabukun Mu wa de simi Re!

AMIN 56 8.7.8.7.D

Mo si gbo bi enipe ohun opolopo eniyan ati bi iron omi pupo, ati bi iro ara nlanla, nwipe, Aleluya nitori Oluwa Olorun wa, Olodumare njoba. Ifi 19:6 1 f Gbogb‘ogun orun nro keke,

E Angeli mu harpu won, Awon mimo nt‘ohun won se, Lati josin t‘o l‘ogo;

Ojo ‗simi t‘Olorun de Ojo t‘o l‘ogo julo, Orun kun fun iho ayo A! b‘isin won ti dun to. 2 f Jek‘a pelu awon t‘orun,

Yin Olorun Oba wa; Jek‘a pa ‗le okan wa mo, K‘a f‘ohun mimo korin Apere ni ti wa le je T‘isimi ti won loke Titi ao fi ri Oluwa Ti a nsi l‘ojukoju 3 mf K‘o to d‘igba na, e jeki

A ma sin l‘ojo keje, K‘a f‘aniyan wa s‘apakan K‘a pe sinu ile Re; O ti pase k‘a ma se be, Y‘o bukun ipejo wa,

(44)

E je k‘a sin li aisare Ere re y‘o je tiwa

AMIN 57 C.M

Inu mi dun nigbati won wi fun mi pe, E je ka lo sile Oluwa. OD 122:1 1 f Bi mo ti yo lati gb‘oro

L‘enu awon ore; Pe, ―Ni Sion‘ni k‘a pe si K‘a p‘ojo mimo mo‖ 2 f Mo f‘onata at‘ekun re;

Ile t‘a se loso, Ile t‘a ko fun Olorun; Lati fi anu han 3 S‘agbala ile ayo na,

L‘eya mimo si lo, Omo Dafid‘wa lor‘ite, O nda ejo nibe. 4 O gbo iyin at‘igbe wa;

Bi ohun eru re Mp Ti nya elese sib‘egbe,

A nyo ni wariri 5 K‘ibukun pelu ibe na

Ayo nigbakugba; K‘a fi ore ati ore, F‘awon ti nsin nibe 6 Okan mi bebe fun Sion‘

Nigbati emi wa; F Nibe ni ‗batan at‘ore

At‘Olugbala wa.

AMIN 58 L.M

Awon ne emi o si mu wa si oke mimo Mi, emi o si mu inu won dun, ninu ile Adua mi. Isa. 56:7 1 f Ayo l‘ojo ‗simi fun mi,

At‘agogo at‘iwasu; P Gbat‘a ba mi n‘nu ‗banuje Mf Awon l‘o nmu inu mi dun 2 Ayo si ni wakati na

Ti mo lo n‘nu agbala Re; Lati mo adun adura Lati gba manna oro Re

(45)

3 f Ayo ni idahun ―Amin‖ T‘o gba gbogbo ile na kan, Lekokan l‘o ndun t‘o nrole, O nkoja lo sodo Baba 4 B‘aye fe f‘agbara de mi

Mo ise ijo mefa re; Mf Oluwa, jo, tu ide na,

K‘o so okan mi d‘ominira AMIN 59 6.6.7.6.7.6.7.6

Ojo keje li ijo isimi Oluwa Olorun Re. Eks. 20:10 1 mf Ose, oso rere,

Iwo ojo simi; O ye k‘a fi ojo kan Fun Olorun rere;

B‘ojo mi ba m‘ekun wa, Iwo n‘oju wa nu; Iwo ti s‘ojo ayo, Emi fe dide re 2 f Ose Ose rere,

A ki yo sise loni; A o fi‘se wa gbogbo Fun aisimi ola,

Didan l‘oju re ma dan, ‗Wo arewa ojo;

Ojo mi nso ti lala, Iwo nso ti simi. 3 f Ose, Ose rere

Ago tile nwipe, F‘eleda re l‘ojo kan, T‘O fun o n‘ijo mefa; A o fi ‗se wa sile, Lati lo sun nibe Awa ati ore wa; A o lo sile adua 4 mf Ose, Ose rere,

Wakati re wu mi; Ojo orun ni ‗wo se; ‗Wo apere orun; Mp Oluwa, je ki njogun

‗Simi leyin iku; Ki nle ma sin O titi, Pelu eniyan Re.

(46)

AMIN 60 6.6.6.6.8.8.

Ki eniyan ki o si ma pa ojo isimi mi mo, ki eniyan ki o si b‘owo fun ibi mimo mi; Emi ni Oluwa. Lef. 19:30 1 f Ji, eyin mimo ji,

Ek‘ojo owo yi, E fi orin iyin A‘tayo juba Re;

Wa bukun ojo t‘a bukun Eya isimi ti orun

2 f Ni oro rere yi L‘Oluwa ji dide, O fo ‗lekun iku, O segun ota wa; O si ngb‘ejo wa ro loke, O nkore eso ife Re. 3 ff Kabiyesi, Oba!

Hosana ndun loke; Aye l‘ohun ‗rele; Si ngba iyin Re ko; Yiye ‗Od‘aguntan t‘a pa, Lati wa, lati joba lea

Amin 61 7.7.7.7.

Nibe ni awon igbekun simi po, nwon ko si gbohun amunisin mo. Jobu 3:18 1 mf Imole, Ojo ‗simi,

Je l‘o ku mo wa l‘oju B‘igbat‘orun iba wo, Fun ajo onigbagbo 2 mf B‘imole ti nrekoja

Oru t‘aso bo aye; Gbogbo nkan dake roro, N‘ipari ojo ‗simi

3 Alafia kun‘aye

Ti Olorun mimo ni, Apere t‘inu okan Ti o bo lowo ese 4 Sibe Emi duro ti

Awon t‘o nsin l‘asale, T‘o gbe okan won s‘oke, To nsare si ebun na

(47)

5 p Jesu je k‘isimi wa Je ti ayo ninu Re, Pp Tit‘okan wa y‘o simi,

Nibi ‗simi ailopin Amin 62 L.M

Ni ijo mefa ni iwo o sise. Eks. 20:9 1 f Ojo isimi Olorun,

Ojo ti o dara julo; Ti Olorun ti fun wa; K‘awa k‘o simi ninu re 2 Ijo mefa l‘O fi fun wa, K‘a fi se ise wa gbogbo; Sugbon ojo keje yato, Ojo ‗simi Olorun ni 3 mf K‘a fi ‗se asan wa sile,

Ti awa nse n‘ijo mefa; Mimo ni ise ti ni, Ti Olorun Oluwa wa. 4 f A para di nissiyi

Ninu ile Olorun wa; Jek‘a korin didun si I, Li owuro ojo oni. 5 Ni kutukutu ‗jo keje

Ni ojo simi mimo Ff Jek‘a jumo korin didun,

Je k‘a si jumo gbadura. AMIN

63 S.M

Won nkigbe li ohun rara, wipe, Yio ti pe to Oluwa? Ifi 6:10 1 f Abe a fe ri O,

Ojo ‗simi rere

Gbogbo ose a ma wipe Iwo o ti pe to?

2 O ko wa pe Kristi F Jinde ninu oku;

Gbogbo ose a ma wipe, Iwo o ti po to?

3 O so t‘ajinde wa

(48)

Gbogbo ose a a wipe; Iwo o ti o pe to? 4 mf Iwo so t‘isimi,

T‘ilu alafia;

T‘ibukun eniyan mimo, Iwo o ti pe to!

AMIN 64 8.7.8.7

Oluwa si simi nijo k‘eje, Eks. 20:11 1 f Akoko odun at‘osu

Gbogbo won l‘Olorun da; Ojumo ni fun ise wa, Oru si ni lati sun 2 O si da ojo isimi;

N‘nu ‗jo meje, O mu ‗kan, K‘eniyan ba le r‘aye se Ati sin olorun won 3 L‘ojo mefa ni k‘a sise

B‘o ti ye ni ki a se; L‘ojo keje je k‘a pejo, Ni ile Olorun wa

4 L‘ojo na yi a ngbadura, A nkorin didun si I A si nyin Olorun l‘ogo T‘o ju ohun gbogbo lo 5 Nissiyi korin iyin,

T‘Olorun Oluwa wa; Ff Korin didun, Korin soke,

Ni yiyin Oluwa wa.

AMN ORIN IYIN

65 S.M

E dide, ki e fi iyin fun Oluwa Olorun yin lae ati laelae; ibukun si ni fun Oruko Re li o li ogo ti oga ju gbogbo ibukun ati yin lo. Neh. 9:5 1 mf Dide, yin Oluwa,

Eyin ayanfe Re, Cr F‘okan, emi at‘ohun re F F‘ibukun f‘Olorun 2 mf B‘O tile ga ju ‗yin

Ati ibukun lo,

(49)

F Ti ki yo si gbega 3 mf Ina ‗mole aye

Lat‘odo Olorun

F To ete wa, m‘okan soji, Di M‘ero wa lo s‘orun 4 cr Olorun, l‘agbara,

F Orin, igbala wa;

Ff Ki gbogb‘ agbara wa kede Ife Re n‘nu Kristi

5 f Dide, yin Oluwa, Juba Olorun re; Yin Oruko Re t‘ologo Lati isiyi lo.

AMIN 66. 12.10.12.10. D

E fi iyin fun Oluwa. OD. 106:1

1 f Fi iyin fun Jesu, Olurapada wa, Ki aye k‘okiki ife Re nla,

Fi iyin fun! Eyin Angeli o‘logo, F‘ola at‘ogo fun oruko Re Mf B‘Olus‘agutan, Jesu y‘o to

Omo Re,

L‘apa Re l‘o ngbe won le l‘ojojo; Eyin eniyan mimo ti ngb‘oke Sion; f Fi iyin fun pelu orin ayo

2 Fi iyin fun, Jesu Olurapda wa, Mp Fun wa, O t‘eje Re sile, O ku, Cr On ni apata, ati reti‘gbala wa, F Yin Jesu ti a kan m‘agbalebu; Mf Olugbala t‘O f‘ara da irora nla, Di Ti a fi ade egun de l‘ori, P Eniti a pa nitori awa eda Mf Oba ogo njoba titi laelae 3 f Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa

Ki ariwo iyin gba orun kan, Jesu Oluwa njoba lae ati laelae, Se l‘Oba gbogb‘ eyin alagbara; A segun iku: fi ayo royin na ka, Mp Isegun re ha da, isa oku?

Cr Jesu ye ko tun si wahala fun wa mo F T‘ori O l‘agbara lati gbala

(50)

67 10.11.10.11 & Ref

Emi o ma korin anu Oluwa laelae. OD 89:1 1 f Em‘o yin Oluwa fun ife Re, A we mi nin ‗eje Olurapada, Mf Eje na t‘o nsan nib‘agbelebu,

A we mi nin‘eje Olurapada, F‘ Ogo, Ogo fun Od‘agutan

O gba mi l‘owo ese mo si di mimo, Ff Ogo, Ogo, Ogo, f‘Od‘agutan,

A we mi nin‘eje Olurapada 2 f Ore-Ofe mu mi sunm‘odo Re,

A we mi nin‘eje Olurapada, Em‘o korin soke, aye y‘o gbo, A we mi nin‘eje Olurapada 3 Alafia wo l‘o to yi l‘okan mi?

A we mi nin‘eje Olurapada; Ayo mimo na ko se f‘enu so, A we mi nin‘eje Lurapada, 4 ff Emi o ma gb‘ohun iyin s‘oke,

A we mi nin‘eje Olurapada, Okan mi y‘o ma korin lojojo A we mi nin‘eje Olurapada.

AMIN 68 11.11.11.11 & Ref

E korin titun si Oluwa; nitori O ti se ohun iyanu. OD 98:1 1 f Eyin Oba Ogo, On ni Olorun,

Yin I fun ‗se ‗yanu ti O ti fi han, O wa pel‘awon ero mimo l‘ona O si je imole won l‘osan l‘oru Eyin angeli didan lu duru wura, Ki gbogbo nyin juba t‘e nwo oju Re, Ni gbogbo ‗joba Re, b‘aye ti nyi lo, Ise Re y‘o ma yin,

Ise Re y‘o ma yin,

Fi ibukun fun Oluwa okan mi 2 E yin fun ‗rapada, ti gbogbo okan,

E yin fun orisun imularapa Fun inu rere ati itoju Re, Fun ‗daniloju pe O ngbo adura, 3 E yin fun idanwo, bi okun ife,

T‘o nso wa po mo awon ohun orun, Fun ‗gbogbo ti nsegun ‗reti ti ki sa

(51)

Fun ile Ogo t‘O ti pese fun wa. Amin 69 L.M & Ref

Oruko Oluwa ni ki ayin. OD. 113:3 1 f B‘oruko Jesu ti dun to,

Ogo ni fun Oruko Re O tan banuje at‘ogbe Ogo ni fun Oruko Re

Ogo f‘oko Re, Ogo f‘oko Re, Ogo f‘oruko Oluwa

Ogo f‘oko Re, Ogo f‘oko Re, Ogo f‘oruko Oluwa

2 O wo okan to gb‘ogbe san Ogo ni fun Oruko Re Onje ni f‘okan t‘ebi npa, Ogo ni fun Oruko Re 3 O tan aniyan elese,

Ogo ni fun oruko Re O fun alare ni simi Ogo ni fun oruko Re 4 Nje un o royin na f‘elese,

Ogo ni fun Oruko Re Pe mo ti ri Olugbala Ogo ni fun Oruko Re.

AMIN 70 6.6.8.4. D

E yin oruko Oluwa Olorun yin, eniti o fi iyanu ba yin lo. Joe 2:26 1 f Yin Olorun Abra‘am,

Ti O njoba l‘oke Eni t‘O ti wa titi lae Olorun ‗fe

―Jehofa nla Emi‖ Gbogbo eda jewo, Mo fi ‗bukun Re Titi laelae

2 mf Yin Olorun Abra‘am, Nip‘ase Eni ti

Mmo dide, mo si wa ‗tunu Lowo ‗tun Re;

Mo ko aye sile; Ogbon at‘ola re; On nikan si ni ipin m At‘asa mi

(52)

3 f On na ti se ‗leri; Mo gbekele eyi, U n I fi iye idi goke Lo si orun

Un o ma wo oju Re Un o si yin ipa Re, Un o korin ‗yanu to‘or‘ofe Titi laelae

4 di B‘agbara eda pin, T‘aye at‘esu nde, Un o d‘ojuko ona kenan‘ Nipa ‗se Re

Un o re odo koja Bi Jesu wa lokan Un o koja n‘nu igbo didi Lo s‘ona mi.

5 mf Oba Oke orun Olor‘Angeli nke

P Wipe ―Mimo, Mimo, Mimo‖ Oba titi

Cr En ‗ti ki yi pada, F Ti y‘o si wa laelae Ff Jehofa Baba, ―Emi ni‖

Awa yin O

6 f Gbogbo ‗gbe asegun Yin Olorun loke, Baba, Omo at,Emi, ni Won nke titi

Ff Yin Olorun Abra‘am! Un o ba won korin na, Tire l‘agbara at‘ola Pelu iyin.

AMIN 71 7.7.7.7

Nitori ti anu Re duro laelae. OD 136:1 1 mf E je k‘a f‘inu didun

Yin Oluwa Olore Anu Re, O wa titi Lododo dajudaju

2 On nipa agbara Re

F‘imole s‘aye titun Anu Re, O wa titi, Lododo dajudaju,

(53)

3 O mbo gbogb‘eda ‗laye, O npese fun aini won, Anu Re, O wa titi Lododo dajudaju 4 cr O bukun ayanfe Re

Li agiju iparun Anu Re, O wa titi Lododo dajadaju 5 f E je k‘a f‘inu didun

Yin Oluwa Olore, Anu Re, O wa titi Lododo dajudaju

Amin 72 L.M

E ho iho ayo si Oluwa, eniyan ile gbogbo. OD 100:1 1 f Niwaju ite Jehofa,

E f‘ayo sin, Orin‘ede Mo p‘Oluwa, on nikan ni, O le da, O si le parun 2 mp Ipa Re, laisi ranwo wa,

F‘amo da wa ni eniyan; P Nigba t‘a sako b‘aguntan Cr O tun a mu si agbo Re, 3 f A o f‘orin Sunmo ‗le Re,

Lohun giga l‘ao korin; Ile, ‗legbarun ahon re, Y‘o fiyin kun agbala Re 4 Ase Re gboro k‘agbaye,

Ife Re po b‘ayeraye; Oto Re y‘o duro laelae Gbat‘odun o dekun ‗yipo

AMIN 73 C.M

Emi o ma fi ibukun fun Oluwa nigbagbogbo OD 34:1 1 mf N‘nu gbogbo ayida aye

Ayo on wahala; Cr Iyin Olorun ni y‘o ma

Wa l‘enu mi titi

2 f Gbe Oluwa ga pelu mi, Ba mi gb‘oko Re ga:

(54)

F O si yo mi kuro 3 Ogun Olorun wa yika

Ibugbe Oloto; Eniti o ba gbekele, Yio ri igbala

4 mf Sa dan ife Re wo lekan ‗Gba na ‗wo o mo pe, Awon t‘o di oro Re mu Nikan l‘eni ‗bukun 5 mf E beru Re, eyin mimo,

Eru miran ko si;

Cr Sa je ki ‗sin Re j‘ayo yin F On y‘o ma tojun yin

AMIN 74 C.M

Kili emi o fi fun Oluwa, nitori gbogbo ore Re simi? OD 116:12 1 f Fun anu t‘o po b‘iyanrin,

Ti mo ngbo lojumo; Lat‘odo Jesu Oluwa; Ki l‘emi o fi fun? 2 p Kini un o fi fun Oluwa,

Lat‘inu Okan mi? Ese ti ba gbogbo re je, Ko tile jamo nkan 3 cr Eyi l‘ohun t‘emi o se

F‘ohun t‘O se fun mi: Emi o mu ago igbala, Un o kepe Olorun 4 mf Eyi l‘ope ti mo le da,

Emi osi, are;

Em‘o ma soro ebun Re, Un o si ma bere si. 5 Emi ko le sin boti to,

Nko n‘ise kan to pe, F Sugbon em‘o sogo yi pe,

Gbese ope mi po

AMIN 75 C.M

(55)

1 f Emi ‗ba n‘egberun ahon, Fun ‗yin Olugbala, Ogo Olorun Oba mi, Isegun ore Re.

2 p Jesu t‘o seru wa d‘ayo T‘o mu banuje tan Orin ni l‘eti elese Cr iey at‘ilera

3 mf O segun agbara ese O da onde sile, Di Eje Re le w‘eleri mo, P Eje Re seun fun mi 4 cr O soro, oku gb‘ohun Re,

O gba emi titun, Onirobinuje y‘ayo, Otosi si gbagbo 5 f Odi, e korin iyin re,

Aditi, gbohun Re; Afoju, Olugbala de, Ayaro, fo f‘ayo

6 Baba mi at‘Olorun mi, Fun mi ni ‗ranwo Re; Ff Ki nle ro ka gbogbo aye,

Ola oruko Re.

AMIN 76 610.10.11.11

Oluwa, Olorun mi, Iwo tobi jojo. OD. 104:1 1 f E wole f‘Oba, Ologo, julo,

E korin ipa ati ife Re; Alabo wa ni at‘Eni igbani, O ngbe ‗nu ogo, Eleru ni iyin 2 E so t‘ipa Re, e so t‘ore Re;

‗Mole l‘aso Re, gobi Re orun, Cr Ara ti nsan ni keke ‗binu Re je,

Ipa ona Re ni a ko si le mo 3 m Aye yi pelu ekun ‗yanu Re

Olorun agbara Re l‘o da won, O fi idi re mule, ko si le yi; O si f‘okun se aso igunwa Re 4 cr Enu ha le so ti itoju Re?

(56)

Ninu afefe ninu imole; Di Itoju Re wa nin‘odo ti o nsan P O si wa ninu iri ati ojo

5 mp Awa erupe aw‘alailera ‗Wo l‘a gbekele, O ki o da ni Cr Anu Re rorun o si le de opin F Eleda, Alabo, Olugbala wa 6 ff ‗Wo Alagbara Onife jule

B‘awon Angeli ti nyin O loke Di Be ‗awa eda Re, niwon t‘a le se Cr A o ma juba Re, a o ma yin O

AMIN 77 C.M

Oun li Oluwa awon luwa ati Oba awon oba. Ifi. 17:14 1 f Gbogbo aye, gbe Jesu ga,

Di Angel‘, e wole fun; Cr E mu ade Oba Re wa, F Se l‘Oba awon Oba 2 mf E se l‘Oba ein Martyr,

Ti npe ni pepe Re; Cr Gbe gbongbo igi, Jese ga F Se L‘Oba awon oba 3 mf Eyin iru omo Israeli‘,

Ti a ti rapada;

Cr E ki Eni t‘o gba yin la, F Se l‘Oba awon oba. 4 p Gbogbo eniyan elese

Ranti ‗banuje yin; Cr E ti ‗kogun yin s‘ese Re, F Se l‘Oba awon oba 5 ff Ki gbogbo orile ede,

Ni gbogbo agbaye, Ki won ki, ‗‖kabiyesile‖ Se l‘Oba awon oba 6 mf A ba le pel‘awon t‘orun

Lati ma juba Re; Cr K‘a bale jo jumo korin, Ff Se l‘Oba awon oba

AMIN 78 8.7.8.7.8.7

(57)

Mo gbohun nla kan ti opolopo eniyan Lorun, wipe Aleluya. Ifi 19:1 1 f Aleluya! Orin t‘o dun,

Ohun ayo ti ki ku; Aleluya! Orin didun, A‘won t‘o wa lorun fe; N‘ile ti Olorun mi ngbe Ni won nko tosantoru 2 Aleluya! Ijo t‘orun,

E le korin ayo na Aleluya! Orin ‗Segun Ye awon ta rapada Awa ero at‘aljo Di Iyin wa ko nilari 3 mp Aleluya! Orin ayo

Ko ye wa nigba gbogbo Aleluya! Ohun aro, Da mo orin ayo wa; P Gba t‘awa laye osi yi Di A ni gbawe f‘ese wa 4 cr Iyin dapo m‘adura wa

Gbo tiwa, metalokan! Mu wa de ‗waju Re layo K‘ar‘Od‘aguntan t‘apa F K‘a le ma ko Aleluya

Nibe lae ati laelae

AMIN 79 8.7.8.7.4.7

Fi ibukun fun Oluwa, Iwo okan mi. OD. 103:1 1 f Okan mi yin Oba orun,

Mu Ore wa sode Re, Mp ‗Wo ta wosan, t‘a dariji Cr Tal‘aba ha yin bi Re?

Yin Oluwa, Yin Oluwa F Yin Oba Ainipekun 2 mf Yin fun anu t‘o fi han

F‘awon Baba ‗nu ponju; Yin l‘Okan na ni titi O lora lati binu F Yin Oluwa, Yin Oluwa,

Ologo n‘nu otito 3 p Bi Baba ni O ntoju wa

(58)

Jeje l‘o ngbe wa lapa Re O gba wa lowo ota, Yin Oluwa, Yin Oluwa Anu Re, yi aye ka 4 ff Angel, e jumo ba wa bo

Eyin nri lojukoju Orun, Osupa, e wole Ati gbogbo agbaye E ba wa yin, E ba wa yin Olorun Olotito.

AMIN 80 L.M

Emi o so ti iseun ife Oluwa. Isa. 63:7 1 f Ji, Okan mi, dide l‘ayo,

Korin iyin Olugbala, Ola Re bere orin mi; P ‗Seun ife Re ti po to! 2 mf O ri, mo segbe n‘isubu,

Sibe O fe mi l‘a fe tan O yo mi ninu osi mi; P ‗Seun ‗fe Re ti tobi to! 3 mf Ogun ota dide simi,

Aye at‘esu ndena mi, On mu mila gbogbo Re ja ‗Sun ‗fe Re ti n‘ipa to! 4 f ‗gba ‗yonu de b‘awosanma

T‘o su dudu t‘o nsan ara O duro ti mi larin re; ‗Seun ‗fe Re ti dara to! 5 ‗Gba gbogbo l‘okan ese mi,

Nfe ya l‘eyin Oluwa mi Sugbon bi mo ti ngbagbe Re Iseun Ife Re ki ye

AMIN 81 7.7.8.7.D

Ninu iponju li awa o de Ijoba orun. Ise A. 14:22 1 f Olorin ijo t‘orun

L‘ayo l‘a wole fun O, Ki O to de, Ijo t‘aye; Y‘o ma korin bi t‘orun‘ Ff A gbe okan wa s‘oke

(59)

Ni ‗reti t‘o ni ‗bukun, Awa kigbe, awa f‘iyin F‘Olorun igbala w 2 ff ‗Gbat‘ awa ninu ‗ponju

T‘ a nkoja ninu ina Cr Orin ife l‘awa o ko

Ti o nmu wa sun mo O; F Awa sa pe, a si yo

Ninu ojurere Re; Ff Ife t‘o so wa di Tire,

Y‘o se wa ni Tire lae 3 p Iwo mu awon eniyan Re;

Koja isan idanwo, cr A ki o beru wahala,

Tori O wa nitosi mf Aye, ese, at‘Esu.

Kojuja si wa lasan f L‘agbara Re a o segun

A o si ko orin Mose. 4 mf Awa figbagbo r‘ogo, Ti o tun nfe fi wa si; cr A kegan aye nitori

Ere nla iwaju wa p Bi0 ba si ka wa ye

Awa pelu Stefen t‘o sun F Y‘o ri O bi O ti duro

Lati pe wa lo s‘orun.

Amin.

82 L.M.

Efi ayo sin Oluwa OD. 100:2.

1 f Gbogbo eyin ti ngbe aye E f ayo korin s‘Oluwa; F‘iberu sin, e yin l‘ogo E wa s‘odo Re, k‘e si yo. 2 Oluwa, On ni Qlorun,

Laisi ‘ranwo wa O da wa; Agbo Re ni wa, O mbo wa; O si fi wa s‘agutan Re. 3 Nje, f‘iyin wo ile Re wa

F‘ayo sunmo agbala Re; Yin, k‘e bukun oruko Re, ‘Tori o ye be lati se.

(60)

4 Ese! rere l‘Olorun wa, Anu Re o wa titi lae, Oto Re ko fi ‘gbakan ye, O duro lat‘ irandiran.

Amin. 83

8.8.6.

Emi o Soro iyin olanla Re

ti o logo, ati ti ise iyanu Re. OD. 145:5. 1 mf S i O Olutunu Orun

Fun ore at‘agbara Re, F A nko, Aleluya. 2 Si O, ife enit‘O wa

Ninu Majemu Olorun A nko, Aleluya. 3 Si O, agbara Eni ti

O nwe ni mo, t‘o nwo ni san A nko, Aleluya.

4 Si O, Oluko at‘ore. Amona wa toto d‘opin, A nko, Aleluya.

5 mf Si O, Eniti Kristi ran, F Ade on gbogbo ebun Re, ff A nko, Aleluya.

Amin. 84

11.12.12.10.

Won ko simi li osan ati li oru wipe, Mimo, Mimo, Mimo,

Oluwa Olorun Olodumare. Ifi. 4:8.

1 p M imo, Mimo, Mimo Olodumare mf Ni kutukutu n‘Iwo O gbo orin wa; p Mimo, Mimo, Mimo! Oniyonujulo, f Ologo meta, lae Olubukun.

2 mf Mimo, Mimo, Mimo! awon t‘orun nyin Won nfi ade wura won le ‗le yi ‗te ka cr Kerubim, Serafim nwole niwaju Re f.di Wo t‘o ti wa, t‘O si wa titi lae.

(61)

Bi oju elese ko le ri ogo Re

mf Iwo nikan l‘O mo, ko tun s‘elomiran Pipe ‘nu agbara ati n‘ife

4 f Mimo, Mimo, Mimo! Olodumare ff Gbogbo ise Re n‘ile l‘oke l‘o nyin O f.cr Mimo, Mimo, Mimo! Oniyonu julo ff Ologo meta lae Olubukun! Amin. 85 6.6.4.6.6.6.4.

Tani ki yio beru, Oluwa ti ki yio si fi ogo fun oruko Re?

Nitoripe iwo nikan soso ni Mimo. Ifi. 15:4. 1 f Baba oke orun

T‘imole at‘ ife Eni ‘gbani

‘MOLE t‘a ko le wo

Ife t‘a ko le so IWO Oba airi

Awa yin O. 2 Kristi Omo laelae

‘WO l‘o di eniyan

Olugbala Eni giga julo, Olorun Imole Ai da at‘ailopin A ke pe O. 3 f Iwo Emi Mimo,

T‘ina Pentikosi Re Ntan titi lae. Ma sai tu wa ninu p L‘aye aginju yi cr ‘Wo l‘a fe, ‘Wo la nyin

A juba Re. 4 f Angel e lu duru,

K‘orin t‘awa, ti nyin p Jumo dalu;

Ogo fun Olorun ff Metalokan soso; A yin O tit‘ aye Ainipekun.

Amin.

86 7.7.7.5.

(62)

WON o si wa si Sioni ti awon ti orin;

ikanu ati ofo yio fo LO. Isa. 51:11.

1 f Olorun Metalokan, Oba ile at‘okun, Gbo ti wa bi a ti nko Orin iyin Re.

2 f ‘Wo imole l‘owuro Tan ‘mol? Re yi wa ka Je ki ebun rere Re p M‘aya wa bale.

3 F ‘WO ‘mole ni gb‘orun WO

K‘a ri idariji gba Ki alafia Orun p F‘itura fun wa. 4 f Olorun Metalokan!

Isin wa l‘aye ko to! A nreti lati dapo Mo awon t‘orun

Amin.

87 6.6.6.6.8.8.

E fi iyin fun Oluwa. OD. 146:1. 1 mf A Fiyin ailopin

Fun Olorun Baba, Fun ore aye wa At‘ireti t‘orun,

O ran Qmo Re ayanfe p Lati ku fun ese aye. 2 f A fiyin ailopin

Fun Olorun Omo P T‘o feje Re ra wa,

Kuro ninu egbe, Nisiyi, O wa, O njoba O nri eso irora Re 3 f A f‘iyin ailopin

Fun Qlorun Emi, Eni f agbara Re SO elese d‘aye;

O pari ise igbala O si fayo Orun k‘okan. 4 f A f‘ola ailopin

(63)

‘WO Ologo meta

Sugbon Qkan soso, B‘O ti ju imo wa lo ni, ff A o ma figbagbo yin O,

Amin

88 7.7.7.7.

Eniti o nfi onje fun eda gbogbo: nitori anu Re duro laelae. OD. 136:25.

1 f Yin Qlorun Oba wa, E gbe ohun iyin ga, Anu Re, o wa titi; L‘ododo dajudaju. 2 mf Yin Enit‘o da orun Ti o nran lojojumo, F Anu Re, o wa titi;

L‘ododo dajudaju. 3 mp Ati osupa l‘oru,

Tio tan ‘mole jeje, F Anu Re,owa titi

L‘ododo dajudaju. 4 mf Yin Enit‘om‘ojo ro,

T‘o mu irugbin dagba, F Anu Re, o wa titi:

L‘ododo dajudaju. 5 mf Enit‘ o pase fun ‗le

Lati mu eso po si; F Anu Re, o wa titi;

L‘ododo dajudaju. 6 f Yin fun ikore oko,

O mu ki aka wa kun, Anu Re, o watiti, L‘ododo dajudaju. 7 mp Yin f onje t‘o ju yi lo,

Eri ‘bukun ailopin F Anu Re, o wa titi; L‘ododo dajudaju. 8 un Ogo f Qba olore

Ki gbogbo eda gberin, Ogo fun Baba, Omo At‘Emi: Metalokan.

(64)

Amin. 89

6.7.6.7.6.6.6.6.

Olorun yi, Olorun wa ni lae ati laelae. OD. 48:14. 1 f A f‘ope f‘Olorun,

L‘okan ati l‘ohun wa. Eni s‘ohun ‘yanu, N‘nu eni t‘araye nyo; mf ‘Gbat‘a wa L‘om‘owo On na l‘ontoju wa 0 si nf‘ ebun ife Se 'toju wa sibe. 2 mf Qba Onib‘ore Ma fi wa sile laelae, Ayo ti ko l‘opin On ‘bukun y‘o je ti wa Pa wa mo n‘nu ore To wa, gb‘a ba damu; Yo wa ninu ibi L‘aye ati l‘orun. 3 un K‘a fiyin on ope,

ff I‘Olorun, Baba, Omo, Ati Emi mimo; Ti Oga julo lorun, Olorun kan laelae,

Amin 90 C.M

Emi o si fi Ota sarin iwo ati obirin na, ati sarin iru-Omo re ati iru-Omo re. On o foo li ori, iwo yio si pa a ni gigise Gen. 3:15.

1 f Iyin f Eni mimo julo L‘oke ati ni ‗le;

Qro Re gbogbo je ‘yanu, Gbogb‘ ona Re daju. 2 mf Ogbon Olorun ti po to

p ‘Gbat‘ eniyan subu; cr Adam‘ keji wa s‘oju ‘ja . f Ati lati gbala.

3 mf Ogbon ife! p‘eran ara p T‘o gbe Adam‘ subu cr Tun b‘ota ja ija otun

(65)

f K‘o ja, k‘o si s‘egun. 4 mf Ati p‘ebun t‘o j‘or-ofe

So ara di otun p Olorun papa tikare

J‘Olorun ninu wa. 5 mf Ife ‘yanu! ti Eni ti O pa ota eniyan Ninu awo awa eniyan Je irora f‘eniyan. 6 p Nikoko, ninu ogba ni

Ati l‘ori igi

cr T‘o si ko wa lati jiya p T‘o ko wa lati ku. 7 f Iyin f‘Eni mimo julo

L‘oke ati nile

Oro Re gbogbo je ‘yanu Gbogb‘ ona Re daju.

Amin

91 8.7.8.7.4.7.

Jesu Kristi, eleri Olooto, Akobi ninu awon oku. Ifi. 1:5. 1 f Oluwa gunwa lori‘te

mf Akobi awon t‘o sun On nikan l‘Onigbeja wa To ngbe wa leke ota cr Aleluya, Aleluya f Jesu li Onje Iye. 2 mf Awa njuba, awa nsape;

F Kabiyesi Oba wa, mf Busi igbagbo wa loni

K‘a le tubo mo O si, F Aleluya, Aleluya

Iwo njoba larin wa. 3 mp Bi a ko tile le ri O

Bit‘awon ti igbani, cr Awa at‘awon Angeli

Nyin iru-omo Jese. Aleluya, Aleluya, TEWO gba ijosin wa.

4 Od‘agutan t‘a fi rubo Ti s‘etutu f‘ese wa

(66)

Ko tun si ebo miran mo Eje Re ti to fun wa. Aleluya, Aleluya, Eje na lo nwe wa mo. 5 O nfi onje iye bo wa

Manna didun lat‘orun K‘orun at‘aye korin na Orin ‘yin s‘Od‘agutan. Aleluya, Aleluya,

O jinde, O si goke.

Amin.

92 8.6.8.6.7.7.7.4. and Ref.

Je ki gbogbo eniyan ki o yin O. OD. 67:3.

1 f Gbe Oluwa ga pelu mi Eyin eniyan Re

Ki gbogbo eda alaye Ma yo l‘oruko Re Fun ife ti 0 nfihan Fun isimi l‘okan wa Fun igbala kikun Re, Tire l‘ope

Ki gbogbo wa f ope fun Ki gbogbo wa fope fun Ki gbogbo wa yin oruko Oluwa wa

Titi laelae, ani, titi laelae Ki gbogbo wa f‘ope fun Ki gbogbo wa f‘ope fun Ki gbogbo wa yin oruko Oluwa Titi laelae.

2 Eyin fun iwa-mimo Re, Fun ore-ofe Re,

Korin iyin fun eje Re To fi ra wa pada Ife lo fi wa wa ri Ninu ira ese wa O f‘ona iye han wa E fope fun.

3 Emi ‘ba l‘egberun ahon, Nko le royin na tan; Ife Re si mi po jojo, Ago ‘bukun mi nkun, Ore-ofe ti ki ye,

(67)

Alafia bi odo Lat‘ odo Olubukun; E fope fun.

Amin. 93 11.11.11.11. & Ref.

E fi ogo fun Oluwa. OD. 29:2.

1 f ' O go ni f‘Oluwa to se ohun nla Ife lo mu k‘O fun wa ni OmO Re,

Enit‘O f‘emi Re le ‗le f‘ese wa To si silekun iye sile fun wa. Ff Yin Oluwa, Yin Oluwa,

F‘ iyin fun Oluwa, ff Yin Oluwa, Yin Oluwa,

E YO niwaju Re,

Ka to Baba wa LO l‘Oruko Jesu,

Je k‘ a JO f‘ogo fun Onise-‘yanu.

2 f Irapada kikun ti eje Re ra F‘enikeni t‘o gba ileri Re gbo, Enit‘o buruju b‘o ba le gbagbo, Lojukanna y‘o ri idariji gba. 3 f O s‘ohun nla fun wa, O da wa l‘ola

Ayo wa di kikun ninu Omo Re Ogo ati ewa irapada yi

Y‘o ya wa lenu ‗gbat‘ a ba ri Jesu Amin.

94 D.S.M.

Li ori Re re li ade pupo wa. Ifi. 19:12.

1 f E de l‘ade pupo Od‘agutan Baba;

Gbo bi orin orun ti bo Orin gbogbo mole: Ji, okan mi korin T‘Eni to ku fun O,

Se l‘Oba re togajulo Titi ati laelae.

2 f S‘Omo Wundia l‘Qba! Om‘Olorun t‘a bi

Ti ade Re n mi legbe fun Ami isegun R?;

Silo ti a so tele, Eka igi Jese,

Olus‘agutan agbo Re Omo ti Betlehem'.

(68)

3 f S‘Oluwa ye l‘Oba To segun iboji To si ji dide ni ‗SEGUN

F‘awon to wa ‗gbala Orin ogo la nko yi T‘Eni to ku, to ji O ku ko ba mu iye wa O ye ki ‗ku le ku 4 f Se l'Oba alafia!

‗Joba Re k‘ yo lopin; Nibiti ogun wole fun Ife titi iyin

Ati yika ese Re ti a kan niso Egberun ede ni ‘dapo Yo korin didun si. 5 f Oluwa loba

Ti O gunwa loke Se l‘Oba ti a fun l‘oko lyanu ‘ti Ife;

E de l‘ade pupo, Awon ti ngbe aye Ati gbogbo oba aye. N‘ tor‘On l‘Oba eda. 6 f Se l‘Oba gbogbo‘gba,

Qba ayeraye,

Eleda gbogbo irawo, Agba ‘yanu leyi: Olurapada wa! To ku nitori mi; Iyin Re ki yo lopin lae Laelae ati laelae.

Amin.

95 14.14.4.7.8.

Nitori ninu Re li a ti da ohun gbogbo, ohun ti mbe li orun ati ohun ti mbe li aye Kol. 1:16.

1 f Y in Oluwa Olodumare, Oba Eleda

Yin Okan mi to r‘On ni ‘lera ati ‘gbala re

Arakunrin,

Arabinrin sunmo ‘hin F‘ayo at‘orin juba Re

(69)

2 f Yin Oluwa, Eni t‘Ojoba lor‘ ohun gbogbo

To dabobo, to si gbe o ro labe iye Re

O ha ri pe?

Gbogb‘ ohun toto lo se B‘O ti lana n‘ipase.

3 f Yin Oluwa to mbukun ‘se re to si ngbeja re;

L‘otito ire ati anu Re nto o leyin ‘Gbana ronu

Ohun t‘Oluwa le se Eni to fe o, t‘O yan o. 4 f Yin Oluwa! Ki gbogb‘ eya

ara mi juba Re

Ki gbogbo ohun t‘o l‘emi wa pelu iyin Re.

Je ki iro

Amin dun jake jado, Layo lao juba Re titi.

Amin. 96 8.7.8.7.4.7.

Oluwa jOba: O joko larin a won Kerubu. OD. 99:1. 1 mp O lorun Oluwa l‘Oba

cr Aye mbe niwaju Re: Nibi t‘awon angel‘ nsin I, L‘O gunwa ni ite Re Eni mimo;

Obangiji, On l‘Oba. 2 f Oba ogo li Olorun,

Sion, royin Re k‘aye; Isra-eli ti igbani, Kede itan oto Re: Eni mimo,

Mimo li oruko Re. 3 Li atijo, ni ‘gba ewu

T‘awon ojise Re be,

O gbo ‘gbe awon eniyan Re, N‘nu eru Won, O dahun, Eni mimo;

Won ri n‘tosi‘gba won p‘E. 4 mf Awon l‘afun 1‘ofin mimo

(70)

Ilana mimo ti won ru, p Mu ki O binu si won:

Eni mimo;

Won kanu fun ese won. 5 cr Sugbon Baba won fiji won,

‘Gba won tun saferi Re mf O mura tan lati gba won f O f‘ife gba won pada:

Eni mimo;

mf Awa na nw‘ or‘-ofe Re. 6 Baba wa n‘iyonu n‘nu Krist‘,

Y‘o mu ileri e? se:

F Wa, k‘a gbe ga, gbogb‘alaye; E wa soke mimo Re!

Eni mimo;

E sin loke mimo Re

Amin.

97 C.M.

Emi o ma korin anu Oluwa laelae. OD. 89:1. 1 mf Olorun ‘gbat‘ okan mi wo

Gbogbo anu Re nla, Iran na mu ki emi kun Fun ‘yanu, ‘fe iyin. 2 f Itoju Re fi aimoye

Itunu f‘okan mi,

K‘okan omode mi to mo ‘Bi ti ‘re na ti nsan. 3 mf L‘ona yiyo odomode

Mo sare laiwoye; 'OWO anu Re l‘o to mi

Titi mo fi dagba. 4 Larin ewu, ati iku,

O nto isise mi; Ati n‘nu ikekun ese T‘o li eru julo

5 mp Nigbat‘ aisan je mi l‘ara, ‘Wo tun fun mi lokun ‘Wo f or‘-ofe mu mi soji Gbat‘ ese bori mi.

6 mf Fun egbegberun ebun Re, Mo nsope lojojo;

(71)

Ti ngba won pel ‘ ayo. 7 Ni gbogbo igba aye mi

Un o lepa ore Re; di Leyin iku, l‘aye ti mbo, cr Un o tun ore Re SO.

8 f U n ma korin ope si O, Titi ayeraye;

ff Sugbon ayeraye ko to So gbogbo iyin Re!

Amin

98 C.M.

Kili emi o san fun Oluwa nitori gbogbo ore Re si mi. OD. 116:12. 1 mf K ini un o fun Olorun mi

Fun gbogbo anu Re?

Un o gba ebun Re, un o si fi Irele bere si.

2 cr Ago or‘-ofe igbala L‘emi o f‘ope gba, Un o feyinti iieri Re, Uno si wa f‘ogo Re. 3 mf Loju awon eniyan Re

Ni un o san eje mi, Uno f‘ara mi on ini mi Fi josin f‘Olorun.

4 mp Baba, gbogb‘ ohun ti mo ni ‘Wo l‘o fijinki mi;

Mo je omp Re laye yi, ‘Wo si ra mi pada. 5 Owo Re l‘o da mi, lo si

Da mi n‘de n‘nu ese; Anu Re t‘o tu ide mi Si ti de mi mo O 6 f Olorun Olodumare mi,

Uno ma kokiki Re, Enu y‘o ru ebo iyin, Un o kepe oko Re. 7 ff E f‘iyin f‘OIorun ife

T'o f‘ese mi ji mi, Titi ao pelu ‘jo toke Ko orin ti orun.

Amin. 99. 11.11.11.11.

(72)

Fun Oba ayeraye, aidibaje, airi, Olorun kansoso ni Ola ati ogo wa fun lae ati laelae. I Tim. 1:17.

1 mf Oba aiku, airi, orisun ogbon To wa n‘nu imole t‘oju kole wo, Olubukun julo, Ologo julo, Alagbara, 0lusegun, ‘WO la yin.

2 Laisimi, laiduro, ni idakeje, O njoba LO,O ko si se alaini;

Giga ni idajo Re bi oke nla, Ikuku Re b‘isun ire at‘ife. 3 f O nte gbogbo eda alaye lori

Nipa imisi Re won ngbe igbe won A ndagba, a ngbile bi ewe igi Asi nro; sugbon bakanna l‘Olorun 4 f Baba nla Ologo Imole pipe

AWON angeli Re wole l‘ese Re

Iyin wa la mu wa, JO ran wa l‘owo

K‘a ler‘ogo imole to yi O ka

Amin 100

7.4.7.4.5.7.4.

Ki iru awon ti of fe igbala re ki o ma wi nigbagbogbo pe: "Ki a gbe Olorun ga. ‖ OD. 70:4.

1 f O ba ogo, alafia, U no feran Re; Ife na ki y‘o dekun, Un o sunmo 0; N‘tori O ti gbebe mi, O ti gb‘ohun mi; O ka iwe aya mi, O da mi n'de. 2 Fun idasile yi ni

Un o korin Re;

Gbogb‘ay o okan mi ni Un o mu fun O;

mp ‘Gbat‘ese min ke kikan, O da mi lare:

mf ‘Gba mo pe O nikoko, O gbebe mi.

Figure

Updating...

References

Updating...

Related subjects :